Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kírísítì Jésù, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀.

2. Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsinmi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bániwí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo.

3. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó oluko jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kùfẹ́ ara wọn.

4. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.

5. Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́nju, ṣe iṣẹ́ ẹ̀fáńjẹ́lísítì, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.

6. Nitorí à ń fí mi rúbọ nisínsinyìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etíle.

7. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́;

Ka pipe ipin 2 Tímótíù 4