Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 3:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù yóò faradà inúnibíni

13. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ̀tàn yóò máa burú síwajú sí i, wọn ó máa tan-nijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ.

14. Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn.

15. Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ ìwé-Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.

16. Gbogbo ìwé-Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.

17. Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.

Ka pipe ipin 2 Tímótíù 3