Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì ti Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.

2. Sí Tímótíù, Ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n:Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kírísítì Jésù Olúwa wa,

3. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn funfun gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsinmi lọ́sàn-án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi.

4. Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀.

Ka pipe ipin 2 Tímótíù 1