Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tẹsalóníkà 3:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣíbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀ta, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún-un gẹ́gẹ́ bí arakùnrin yín.

16. Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

17. Èmi Pọ́ọ̀lù fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe àmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí.

18. Kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú yín.

Ka pipe ipin 2 Tẹsalóníkà 3