9. Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Sàtánì, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́-ìyanu, àdàmọ̀dì àmì àti àdàmọ̀dì idán,
10. Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà.
11. Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìsìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́,
12. Kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú-dídùn nínú ìwà-búburú.
13. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìṣọdi-mímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.
14. Òun ti pè yín sí èyí nípa ìyìn rere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jésù Kírísítì Olúwa wa.
15. Nítorí náà ará, ẹ dúró sinsin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.
16. Ǹjẹ́ kí Jésù Kírísítì Olúwa wa tìkalára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa.
17. Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.