Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tẹsalóníkà 1:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótíù,Sí ìjọ Tẹsalóníkà, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì Olúwa:

2. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa.

3. Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín gbogbo sí ara yín ń di púpọ̀.

4. Nítorí náà, àwa tìkara wa ń fi yín ṣògo nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà nínú gbogbo ìjọ.

5. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé ní torí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà.

6. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,

7. Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì se nígbà ìfarahàn Jésù Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì alágbára.

8. Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìyìn rere Jésù Olúwa wa.

Ka pipe ipin 2 Tẹsalóníkà 1