Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Pétérù 1:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlìí dunjúdunjú síi, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsí gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ́ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín.

20. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àṣọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ́ wòlìí fún rara rẹ̀.

21. Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ̀ wá.

Ka pipe ipin 2 Pétérù 1