Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 7:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run.

13. Nítorí náà, a tí fí ìtùnú yín tù wá nínú.Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Títù ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára.

14. Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójú tì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Títù sì já sí òtítọ́.

15. Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń ránti ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á.

16. Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 7