Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójú tì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Títù sì já sí òtítọ́.