Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 2:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́?

3. Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀: nítorí tí mo ní ìgbẹkẹlé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi.

4. Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹyin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù.

6. Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fí jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un.

7. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.

8. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí Olúwa rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 2