Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 2:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà mo tí pínnú nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fí ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá.

2. Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́?

3. Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀: nítorí tí mo ní ìgbẹkẹlé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi.

4. Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹyin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù.

6. Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fí jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un.

7. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.

8. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí Olúwa rẹ̀.

9. Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé, kí èmi baà lè rí ẹ̀rí dìmú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo.

10. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjín ẹnikẹ́ni, èmí fi jì pẹ̀lú. Èmi ti dárìjìn níwájú Kírítí nítorí yín.

11. Kí Sàtánì má baà rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.

12. Ṣùgbọ́n nígbá ti mo dé Tíróà láti wàásù iyinrere Kírísitì, tí mo sì ríi wí pé Olúwa ti sílẹ̀kùn fún mi,

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 2