Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 11:6-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo.

7. Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìn rere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́.

8. Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbigba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín.

9. Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedóníà wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.

10. Ó jẹ́ òtítọ́, Kírísítì tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Ákáyà.

11. Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.

12. Ṣùgbọ́n ohun ti mo ń ṣe ni èmi yóò sì máa ṣe, kí èmi lè mú ẹ̀fẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fẹ́ ṣẹ̀fẹ̀, pé nínú ohun tí wọ́n ṣògo, kí a lè rí wọn gẹ́gẹ́ bí àwa.

13. Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èkè Àpósítélì àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di Àpósítélì Kírísítì.

14. Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Sátanì, tìkáraarẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dà bí ańgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.

15. Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dà bí àwọn ìrànṣẹ́ òdodo; ìgbẹ́yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

16. Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀.

17. Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí.

18. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú.

19. Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkáraayín jẹ́ ọlọgbọ́n.

20. Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú.

21. Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 11