1. Mo rò wí pé ẹ ó farada díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n ẹ tilẹ̀ ti rí ṣe bẹ́ẹ̀.
2. Nítorí pé èmi ń jówu lórí i yín ní ti owú ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúndíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kírísítì.
3. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Éfà jẹ́ nípaṣẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín sáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajìn fún Kírísítì.
4. Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jésù mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
5. Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn ní ohunkohun sí àwọn àgbà Àpósítélì.
6. Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo.
7. Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìn rere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́.
8. Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbigba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín.
9. Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedóníà wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.