Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Jòhánù 1:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jésù Kírísítì wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ̀tàn àti Aṣòdì sí Kírísítì.

8. Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.

9. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kírísítì, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ.

10. Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú àbọ̀.

11. Nítorí ẹni tí ó bá kí i kú àbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

12. Bí mo ti lẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alabapin pẹ̀lú yín, síbẹ̀èmi kò fẹ́ lo ìwé-ìkọ́wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

13. Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.

Ka pipe ipin 2 Jòhánù 1