orí

  1. 1

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Jòhánù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Alàgbà,Sì àyànfẹ́ obìnrin-ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmí nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;

2. nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

3. Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlààáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.

4. Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pá àṣẹ fún wa.

5. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtèkèkọ́ṣe, pé kí àwá fẹ́ràn ara wa.

6. Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.

7. Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jésù Kírísítì wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ̀tàn àti Aṣòdì sí Kírísítì.

8. Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.

9. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kírísítì, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ.

10. Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú àbọ̀.

11. Nítorí ẹni tí ó bá kí i kú àbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

12. Bí mo ti lẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alabapin pẹ̀lú yín, síbẹ̀èmi kò fẹ́ lo ìwé-ìkọ́wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

13. Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.