Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 5:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹni ti a jẹ́rì rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olupọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.

11. Ṣùgbọ́n kọ̀ (láti kọ orúkọ) àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà ti wọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kírísítì, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó.

12. Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀.

13. Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ile-dé-ilé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ.

14. Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábòójútó ilé, kí wọn má ṣe fi àyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.

15. Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Sàtánì.

16. Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́.

17. Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lu pẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni.

18. Nítorí tí Ìwé-Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹnu.” Àti pé, “ọ̀yà alágbàse tọ́ sí i.”

19. Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì-mẹ́ta.

20. Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 5