Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 1:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.

9. Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá àti àwọn apànìyàn,

10. fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

11. Gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.

12. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kírísítì Jésù Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòótọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀;

13. Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn: ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́.

14. Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.

15. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jésù Kírísítì wá sí ayé láti gba ẹlẹ́sẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.

16. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́sẹ̀ ni kí Jésù Kírísítì fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn.

17. Ǹjẹ́ fún Ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

18. Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Tímótíù ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípaṣẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere;

19. Máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere. Àwọn ẹlòmíràn tanù lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn;

20. Nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Alẹkisáńdérù wà; àwọn tí mo ti fi lé Sàtánì lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọn má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 1