Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tẹsalóníkà 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, Sílásì àti Tímótíù.A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jésù Kírísítì.Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kírísítì kí ó jẹ́ tiyín.

2. Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú.

3. A ń rántí lí àìsinmi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Bàbá iṣẹ́ ìgbàgbọ́yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró sinsin ìretí yín nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.

4. Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Tẹsalóníkà 1