Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 5:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kírísítì Jésù, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkararẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.

11. Tírẹ̀ ni ògo àti agbára títí láé (Àmín)

12. Nítorí Sílà, arákùnrin wa olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkurú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.

13. Ìjọ tí ń bẹ ní Bábílónì, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Máàkù ọmọ mi pẹ̀lú.

14. Ẹ fi ìfẹ́nukònú ìfẹ́ kí ara, yín (Àmín)

Ka pipe ipin 1 Pétérù 5