Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 3:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere?

14. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, àlàáfíà ni: ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú;

15. Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kírísítì bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń bèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.

16. Kí ẹ máa ni ẹ̀rí-ọkàn rere bi wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kírísítì.

17. Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣiṣé búburú lọ.

18. Nítorí tí Kírísítì pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí:

19. Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú:

20. Àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sáà kan ní ọjọ́ Nóà, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba àwọn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ.

21. Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsìnyìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jésù Kírísítì.

22. Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹ́riba lábẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Pétérù 3