Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 9:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe àpósítélì. Dájúdájú àpósítélì ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ àpósítélì mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.

3. Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ Àpósítélì mi.

4. Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí?

5. Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í se onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn Àpósítélì mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kéfà.

6. Ṣé kìkì Bánábà àti èmi ló yẹ kí a máa ṣisẹ́ bọ́ ara wa ni?

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 9