Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 5:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà, àgbérè wa láàrin yín, irú àgbérè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀.

2. Ẹ̀yin ń se ìgberaga, kí ni ṣe tí ojú kò tì yín, kí ẹ sì kún fún ìbànújẹ́, kí ẹ sì rí i pé ẹ yọ ọkùnrin náà tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrin àwọn ọmọ ìjọ yín?

3. Lóòtọ́ èmi kò sí láàrin yín, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jésù Kírísítì, mo tí ṣe ìdájọ̀ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrin yín.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 5