Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 2:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ẹnikẹ́ni tí kò bá jẹ́ ti Ẹ̀mí kò lè gba àwọn ohun tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mi Mímọ́, nítorí wọ́n jẹ́ ohun wèrè sí, kò sì le ye e, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn.

15. Ẹni tí ẹ̀mí ń ṣe ìdájọ́ ohun gbogbo, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a kò ti ọwọ́ ènìyàn dá lẹ́jọ́:

16. “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kírísítì.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 2