Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 15:45-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Ádámù ọkùnrin ìṣáàjú, alààyè ọkàn ni a dá a” Ádámù ìkẹ́yìn ẹ̀mí ti ń fún ní ní ìyè.

46. Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáajú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.

47. Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá, ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.

48. Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.

49. Bí àwa ó sì rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àworán ẹni ti ọ̀run.

50. Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.

51. Kíyesí í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà,

52. Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìdé ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.

53. Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé àra àìkú wọ̀.

54. Ṣùgbọ́n nígbá tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbá náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní iṣẹ́gun.”

55. “Ikú, oró rẹ dà?Ikú, iṣẹgun rẹ́ dà?”

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 15