Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 15:40-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ: ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀.

41. Ọ̀tọ̀ ni ògo ti òòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ sá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

42. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdibàjẹ́; a sí jì í didé ni àìdíbàjẹ́:

43. A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì ji í dìde ní agbára.

44. A gbìn ín ni ara ti ọkàn, a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.Bí ara tí ọkàn bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ.

45. Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Ádámù ọkùnrin ìṣáàjú, alààyè ọkàn ni a dá a” Ádámù ìkẹ́yìn ẹ̀mí ti ń fún ní ní ìyè.

46. Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáajú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.

47. Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá, ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.

48. Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.

49. Bí àwa ó sì rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àworán ẹni ti ọ̀run.

50. Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.

51. Kíyesí í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà,

52. Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìdé ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.

53. Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé àra àìkú wọ̀.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 15