Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 14:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun?

9. Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹyin bá ń fí ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán.

10. Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀

11. Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ itúmọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó já sí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí já sí aláìgbédè sí mi.

12. Bẹ́ẹ̀ si ní ẹ̀yín, bí ẹ̀yín ti ni itara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ síi fún ìdàgbàsókè ìjọ.

13. Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ.

14. Nítorí bí èmí bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkan mi jẹ́ aláìléso.

15. Ǹjẹ́ kín ni èmi ó ṣe? Èmí o fí ẹ̀mí mí gbàdúrà, èmi ó sí fí ọkàn gbàdúrà pẹ̀lú: Èmi ó fi ẹ̀mí kọrin, èmi o sí fi ọkàn kọrin pẹ̀lú.

16. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá sú ìre nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ́ wí?

17. Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítóótọ́, ṣùgbọ́n a kó fí ẹsẹ̀ ẹnikéjì rẹ múlẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 14