Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 14:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fí itará ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa ṣọ tẹ́lẹ̀.

2. Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀;

3. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú.

4. Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ìjọ múlẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa, pẹ̀lúpẹ̀lú láti lè máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ tóbi jú ẹni ti ń sọ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtúmọ̀, kí ijọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.

6. Ǹjẹ nísinsìnyìí, ará, bí mo bá wá sí àárin yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmí óò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá iṣọtẹ́lẹ̀, tàbí nipá ẹ̀kọ́?

7. Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìba à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí?

8. Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun?

9. Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹyin bá ń fí ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 14