Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kírísítì.

2. Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún didi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú sinsin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín.

3. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kírísítì ni orí olukúlúkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kírísítì sì ní Ọlọ́run.

4. Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀.

5. Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí.

6. Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un làti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.

7. Ṣugbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwọrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.

8. Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin,

9. bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin.

10. Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn ańgẹ́lì, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 11