Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 10:22-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ?

23. “Ohun gbogbo ni o yẹ fún mi,” ṣùgbọ̀n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ń gbe ni rò.

24. Má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n kí olúkúkù máa wá ire ọmọnikéji rẹ̀.

25. Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn.

26. Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”

27. Bí ẹnìkẹ̀ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àṣè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rún. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àṣè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.

28. Bí ẹnikẹ́nì bá sì kìlọ̀ fún un yín pé a ti fi ẹran yìí rúbọ sí òriṣà, má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹ̀rí ọkàn tí ó kìlọ̀ fún ọ́ pé a ti fi rúbọ sí òrìṣà.

29. Nǹkan tí ó ṣe pàtàkì ní irú ipò yìí ni ẹ̀rí ọkàn àti èrò ọkùnrin náà, nítorí kì í ṣe ẹ̀rí ọkàn ẹlòmìíràn ní a ó fi dá òmìnira mi lẹ́jọ́.

30. Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, è é ṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búbúrú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.

31. Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkohun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.

32. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ (tí ó lè gbé ẹlòmíràn subú) ìbá à ṣe Júù tàbí Gíríkì tàbí ìjọ Ọlọ́run rẹ̀.

33. Bí ṣè n gbìyanjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 10