Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 8:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkeji rẹ̀; ẹ má fẹ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.

18. Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

19. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà; nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà.”

20. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò ṣa tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú-ńlá púpọ̀.

21. Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú-ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojú rere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’

22. Nítòótọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jérúsálẹ́mù; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojú rere Olúwa.”

23. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

Ka pipe ipin Sekaráyà 8