Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 14:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Júdà pẹ̀lú yóò sì jà ni Jérúsálẹ́mù: ọrọ̀ gbogbo awọn aláìkọlà tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, góòlu, àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

15. Bẹ́ẹ̀ ni àrùn ẹṣin, ìbáákà, ràkúnmí, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àrùn yìí.

16. Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jérúsálẹ́mù yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àṣè àgọ́ náà.

Ka pipe ipin Sekaráyà 14