Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 12:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa fún Íṣírẹ́lì, ni Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mi ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀:

2. “Kíyèsí í, èmi yóò ṣọ Jérúsálẹ́mù dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

3. Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orilẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jérúsálẹ́mù di ẹrù òkúta fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fi dẹ́rù pa ara wọn ni a ó ge sí wẹ́wẹ́,

4. ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fí ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì sí ojú mi sí ilé Júdà, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè.

5. Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.’

6. “Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀.

7. “Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Júdà là ná, kí ògo ilé Dáfídì àti ògo àwọn ara Jérúsálẹ́mù má ba gbé ara wọn ga sí Júdà.

Ka pipe ipin Sekaráyà 12