Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 3:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìun tí ń ké ramúramù,àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkokò àṣálẹ́ ni wọn,wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀.

4. Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga,wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn.Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́,wọ́n sì rú òfin.

5. Olúwa ni àárin rẹ̀ jẹ́ olódodo;kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà.Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀,kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun,ṣíbẹ̀ àwọn aláìsòótọ́ kò mọ ìtìjú.

6. “Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́.Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní ihàtóbẹ́ẹ̀ tí ẹnìkan kan kò kọjá níbẹ̀.Ìlú wọn parun tóbẹ́ẹ̀ tí kò síẹnikan tí yóò sẹ́kù,kò sì ní sí ẹnìkan rárá.

7. Èmi wí fún ìlú náà wí pé‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi,ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúròbí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n níyà tó.Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtaraláti ba iṣẹ́ wọn jẹ́.

8. Nítorí náà ẹ dúró dèmi,” ni Olúwa wí,“títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò dìde si ohun ọdẹ; nítoríìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kíèmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti rú ìbínú jádesórí wọn, àní gbogbo ibínú gbígbóná mi.Nítorí, a ó fi iná owú ibínú jẹ gbogbo ayé run.

9. “Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́,nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa,láti fi ọkàn kan sìnín.

10. Láti òkè odò Etiópíà,àwọn olùsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká,yóò mú ọrẹ wá fún mi.

11. Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútìnítorí gbogbo ìsẹ́ni tí ó ti ṣesí mi, nígbà náà ni èmi yóò mukúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn.Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ní òkè mímọ́ mi.

12. Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútùàti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárin rẹ̀,wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.

13. Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì kì yóò hùwàibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké,bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè níẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rù bà wọ́n.”

14. Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì,kígbé sókè, ìwọ Ísírẹ́lì!Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.

15. Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nìkúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀ta rẹ padà sẹ́yìn. Olúwa, ọba Ísírẹ́lì wà pẹ̀lú rẹ,Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.

Ka pipe ipin Sefanáyà 3