Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 1:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoroọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,ọjọ́ kuru àti òkùnkùn biribiri,

16. ọjọ́ òpè àti ìdágìrì àti ìdágirisí àwọn ìlú olódìàti sí àwọn ìsá gíga

17. Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sóríènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú,nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa.Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí erukuàti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.

18. Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọnkì yóò sì le gbà wọ́n làní ọjọ́ ìbínú Olúwa.Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi ináìjowú rẹ̀ parun,nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sígbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé ayé.”

Ka pipe ipin Sefanáyà 1