Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 94:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i.”

8. Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyànẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

9. Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi?Ẹni tí ó dá ojú?Ó ha lè ṣe láìríran bi?

10. Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí?Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

11. Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;ó mọ̀ pé aṣán ni wọ́n.

12. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tíìwọ báwí, Olúwa,ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin Rẹ;

13. Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14. Nítorí Olúwa kò ní kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀;Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní Rẹ̀ sílẹ̀.

15. Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,àti gbogbo àwọn ọlọ́kàndídúró ṣinṣin yóò tẹ̀ lé e lẹ́yìn.

16. Ta ni yóò dìde fún misí àwọn olùṣe búburú?Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?

17. Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,èmi fẹ́rẹ̀ má a gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́

18. Nígbà tí mo sọ pé “ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ Rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.

19. Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,ìtùnú Rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20. Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Rẹẹni tí ń fí òfin dìmọ̀ ìwà ìkà?

21. Wọ́n kó ara wọn jọ si olódodowọ́n sì ń dá àwọn aláìsẹ̀ lẹ́bi sí ikú.

22. Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹnití mo ti ń gba ààbò.

Ka pipe ipin Sáàmù 94