Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 94:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.

2. Gbé ara Rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;san ẹ̀san fún agbéragaohun tí ó yẹ wọ́n.

3. Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwatí àwọn ẹni búburúyóò kọ orin ayọ̀?

4. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbérága jáde;gbogbo àwọn olùṣebúburúkún fún ìṣògo.

5. Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn Rẹ túútúú, Olúwa:wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní Rẹ̀ lójú.

6. Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,

7. Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i.”

8. Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyànẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

9. Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi?Ẹni tí ó dá ojú?Ó ha lè ṣe láìríran bi?

10. Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí?Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

11. Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;ó mọ̀ pé aṣán ni wọ́n.

12. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tíìwọ báwí, Olúwa,ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin Rẹ;

13. Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14. Nítorí Olúwa kò ní kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀;Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní Rẹ̀ sílẹ̀.

15. Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,àti gbogbo àwọn ọlọ́kàndídúró ṣinṣin yóò tẹ̀ lé e lẹ́yìn.

16. Ta ni yóò dìde fún misí àwọn olùṣe búburú?Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?

17. Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,èmi fẹ́rẹ̀ má a gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́

Ka pipe ipin Sáàmù 94