Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 93:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa ń jọba, ọlá ńlá ní ó wọ̀ ní aṣọ;ọlá ńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọàti ìhàmọ́ra Rẹ̀ pẹ̀lú agbára.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì le è yí.

2. Ìjọba Rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;ìwọ wà títí ayé raye.

3. A ti gbé òkun sókè, Olúwa,òkun ti gbé ohùn wọn sókè;òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.

4. Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo.

5. Ẹ̀rí Rẹ̀ dúró ṣinṣin;ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé Rẹ̀ lọ́sọ̀ọ́fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 93