Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 91:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ,ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ

8. Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹàti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

9. Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò Rẹ,ìwọ fi Ọ̀ga Ògo ṣe ibùgbé Rẹ.

10. Búburú kan ki yóò subu lù ọ́Bẹ́ẹ̀ ni àrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé Rẹ.

11. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì nípa tìrẹláti pa ọ́ mọ ní gbogbo ọ̀nà Rẹ;

12. Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ Rẹ̀ gún òkúta.

13. Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò nì ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 91