3. Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé,ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r,níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí:ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ;wọn o máa yìn ọ́ títí láé.
5. Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹàwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6. Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọwọn sọ ọ́ di kàngaàkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
7. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipátítí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì.
8. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jákọ́bù.
9. Wo àsà wa, Ọlọ́run;fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òroro Rẹ.