Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 84:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ibùgbé Rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa Olódùmarè!

2. Ọkàn mí ń fà nítòótọ́ó tilẹ̀ pòùngbẹ fún àgbàlá Olúwaàyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọ́run alààyè.

3. Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé,ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r,níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí:ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

4. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ;wọn o máa yìn ọ́ títí láé.

5. Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹàwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

6. Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọwọn sọ ọ́ di kàngaàkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;

7. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipátítí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì.

8. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jákọ́bù.

9. Wo àsà wa, Ọlọ́run;fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òroro Rẹ.

10. Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin Rẹju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run miju láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

Ka pipe ipin Sáàmù 84