Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 75:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,a yìn ọ́, nítorí orúkọ Rẹ̀ súnmọ́ tòsí;àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu Rẹ.

2. Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.

3. Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,Èmi ni mo di òpó Rẹ̀ mú ṣinṣin.

4. Èmí wí fún àwọn agbéraga péẸ má ṣe gbéraga mọ́;àti sí ènìyàn búburú;Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.

5. Ẹ máa ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

6. Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé kò ti ìlà-oòrùn wátàbí ní ìwọ̀-oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúsù wá.

7. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdajọ́;Òun Rẹ̀ ẹnìkan sílẹ̀, ó sí ń gbé ẹlòmíràn ga.

8. Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,ọtí wáìnì náà sì pọ́n,ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pòpọ̀ mọ́ òórùn dídùntí ó tú jáde, àti búburú ayé gbogbomú u sílẹ̀ pátapáta.

9. Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn Rẹ títí láé;Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jákọ́bù (Ísírẹ́lì)

10. Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Ka pipe ipin Sáàmù 75