Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 69:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbàmí, Ọlọ́run,nítorí omi tí kún dé ọrùn mi.

2. Mo ń rì nínú ìrà jínjìn,níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.Mo ti wá sínú omi jínjìn;ìkún omi bò mí mólẹ̀.

3. Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,nígbà ti èmi dúró de Ọlọ́run mi

4. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìíwọn ju irun orí mi; lọpúpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,àwọn tí ń wá láti pa mí runA fi ipá mú miláti san ohun tí èmi kò jí.

5. Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú Rẹ.

6. Má ṣe dójú tì àwọn tí ó ní ìrètí nínú Rẹnítorí mi, Olúwa, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun;Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7. Nítorí Rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,ìtìjú sì bo ojú mi.

8. Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

9. Nítorí ìtarà ilé Rẹ jẹ mí run,àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

10. Nígbà tí mo sunkúntí mo sì ń fi ààwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyàèyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

11. Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,àwọn ènìyàn ń pòwe mọ́ mi.

12. Àwọn tí ó jòkòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi niìwọ ni èmi n gbàdúrà mi sí Olúwa,ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbàỌlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi Rẹ,dá mí lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà Rẹ tí ó dájú.

14. Gbá mí kúrò nínú ẹrẹ̀,Má ṣe jẹ́ kí ń rí;gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí o korìíra mi,kúrò nínú ibú omi.

Ka pipe ipin Sáàmù 69