Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 67:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí o sì bùkún fún wakí ó sì jẹ́ kí ojú Rẹ̀ tàn yí wa ká,

2. kí ọ̀nà Rẹ̀ le di mímọ̀ ní ayé,ìgbàlà Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.

3. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;kí gbogbo ènìyàn kí o yìn ọ!

4. Kí orílẹ̀ èdè kí o yọ̀, kí o sì kọrin fún ayọ̀,nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyànìwọ si jọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

5. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela

6. Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè Rẹ̀ wá, Ọlọ́run,Ọlọ́run wa yóò bùkún fún wa.

7. Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 67