Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 57:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,nítorí nínú Rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.Èmi o fi ààbò mí síbi ìyẹ́ apá Rẹtítí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

2. Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run gíga jùlọ,sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ fún mi.

3. Òun yóò ránsẹ́ láti ọ̀run wá,yóò sì gbà mí bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mì mìtilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.Ọlọ́run yóò rán àánú Rẹ̀ àti òdodo Rẹ̀ jáde.

4. Mo wà ní àárin àwọn kìnnìún;mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburúàwọn ènìyàn tí ẹ̀yin wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfàẹni tí ahọ́n Rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

5. Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọkí ògo Rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

Ka pipe ipin Sáàmù 57