Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 47:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyànẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀

2. Báwo ni Olúwa ọ̀gá ògo ti ni ẹ̀rù tóọba ńlá lórí gbogbo ayé

3. Ó ṣẹ́ àwọn orílẹ̀ èdè lábẹ́ waàwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa

4. Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún waọlá Jákọ́bù, ẹni tí ó fẹ́ wa

5. Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀ Olúwa ti òun ti àriwo ipè

6. Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, Ẹ kọrin ìyìnẸ kọrin ìyìn sí ọba wa, Ẹ kọrin ìyìn!

7. Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayéẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Sáàmù!

8. Ọlọ́run jọba lórí gbogbo ayé;Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ Rẹ̀

9. Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọgẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Ábúráhámùnítorí asà ayé ti Ọlọ́run niòun ni ó ga jùlọ.

Ka pipe ipin Sáàmù 47