Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 40:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹtí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,wọn ju ohun tíènìyàn leè kà lọ.

6. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,ìwọ ti sí mi ní etí.Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ni ìwọ kò bèèrè.

7. Nígbà náà ni mo wí pé,“Èmi nìyí;nínú ìwé kíkà nìa kọ ọ nípa temí wí pé.

8. Mo ní inú dídùnláti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ,ìwọ Ọlọ́run mi;Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Ka pipe ipin Sáàmù 40