Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 40:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

2. Ó fà mí yọ gòkèláti inú ihò ìparun,láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,ó sì jẹ́ kí ìgbesẹ̀ mi wà láìfòyà.

3. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.Ọ̀pọ̀ yóò ríi wọn yóò sì bẹ̀rù,wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.

4. Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n ọn-nìtí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọntí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,tàbí àwọn tí ó yapalọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

5. Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹtí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,wọn ju ohun tíènìyàn leè kà lọ.

6. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,ìwọ ti sí mi ní etí.Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ni ìwọ kò bèèrè.

Ka pipe ipin Sáàmù 40