Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 35:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nítorí pé, ní àìnídìí ní wọ́n dẹàwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtòfún ọkàn mi.

8. Jẹ́ kí ìparun kí ó wá síorí wọn lójijì.Àwọ̀n Rẹ̀ tí ó dẹ pamọ́,kí ó mú àwọn tìkálára wọn;kí wọn ṣubú sínú kòtòsí ìparun ara Rẹ̀.

9. Nígbà náà ni ọkàn miyóò yọ̀ nínú Olúwa,àní ayọ̀ ńlá nínú ìgbàlà Rẹ̀.

10. Gbogbo egúngún mi yóò wí pé,“ìwọ Olúwa,ta ni ó dà bí i Rẹ̀?O gba talákà làlọ́wọ́ àwọn tí ó lágbárajù wọ́n lọ,talákà àti aláìnílọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

11. Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;wọ́n bi mi léèrè àwọn ohuntí èmi kò mọ̀.

12. Wọ́n fi búburú san ire fún mi;láti sọ ọkàn mi di òfo.

13. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni,nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn,mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;mo fi ààwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríbaní oókan àyà mi;

Ka pipe ipin Sáàmù 35