Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 31:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,nítorì orúkọ Rẹ máa ṣe ìtọ́ mi tọ́ mi kí o sì ṣe amọ̀nà mi.

4. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,nítorí ìwọ ni ìsádi mi.

5. Ní ọwọ́ Rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;ìwọ ni ó tí rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

6. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fi yè sí òrìṣà tí kò níye lórí;ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

7. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá Rẹ,nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ miìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.

8. Pẹ̀lú ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi àyè ńlá.

9. Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

10. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ miàti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;agbára mi ti kùnà nítorí òṣì mi,egungun mi sì ti rún dànù.

11. Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ọ̀tá mi gbogbo,pẹ̀lú pẹ̀lú láàrin àwọn aládùúgbò mi,mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.

12. Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.

13. Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí miláti gba ẹ̀mi mi.

14. Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ OlúwaMo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ Rẹ;gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá miàti àwọn onínúnibíni.

Ka pipe ipin Sáàmù 31