Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 31:18-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn.wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19. Báwo ni títóbi oore Rẹ̀ ti pọ̀ tó,èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ,èyí tí ìwọ rọ̀jò Rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàntí wọ́n fi ọ́ se ibi ìsádi wọn.

20. Ní abẹ́ ibòji iwájú Rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ síkúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;ní ibùgbé Rẹ o mú wọn kúrò nínú ewukúrò nínú ìjà ahọ́n.

21. Olùbùkún ni Olúwa,nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hànnígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yí ká.

22. Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,“A gé mi kúrò ní ojú Rẹ!”Ṣíbẹ̀ ìwọ́ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánúnígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23. Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́! Olúwa pa olódodo mọ́,ó sì san-án padà fún agbéraga ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́.

24. Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà legbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 31